Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2023

Question 9

 

Rọ́ ìtàn bí Mọrèmi ṣe dá ìlú tirẹ̀ sílẹ̀

Observation

Candidates were required to give account of how Mọrèmi established her own town.

Bí Mọrèmi ṣe dá ìlú tirẹ̀ sílẹ̀ lẹ́yìn tí ó dé ìlú Ìlá:

  1. Mọrèmi fi èròńgbà rẹ̀ hàn fún wọn ní ìlú ìlá pé òun ní i lọ́kàn láti tẹ̀dó sí ìletò tuntun tòun yóò dá sílẹ̀
  2. Nígbà tí ó pé ọjọ́ méje gééré tí Mọrèmi ti dé sí ọ̀dọ̀ Ọ̀ràngún Ilé-ìlá, ló digbá-dagbọ̀n tó mú ìrìn àjò rẹ̀ pọ̀n láti lọ dá ìlú tuntun tiẹ̀ sílẹ̀
  3. Àwọn ènìyàn tí ó tẹ̀lé Mọrèmi láti ìlú Ìlá kò níye; Ifáyẹ́misí àti Ifábùnmi wà nínú àwọn èrò tí ó bá a lọ
  4. Ọlálọmí, ọmọ Ọ̀rànmíyàn tí ó jẹ́ ọ̀dọ́ hánrán-ún ni Mọrèmi fi ṣe olórí ẹ̀ṣọ́ rẹ̀
  5. Lẹ́yìn tí wọ́n ti rin ìrìn àjò fún odidi ọjọ́ kan gbáko, wọ́n dé ibì kan báyìí lábẹ́ igi
  6. Ọ̀tún Ọ̀délé tí ó jẹ́ olóyè nínú ikọ̀ náà ní kí Mọrèmi yọ̀nda ẹyẹlé funfun kan tó mú lọ́wọ́
  7. Èyẹlé náà fò pììrìpì, wọ́n sì ń fojú tọ ẹyẹlé náà lọ bó ti ń lọ sí sánmọ̀.
  8. Nígbà tí wọ́n rí i lọ́ọ̀kàn pé ó ti bà sí orí igi ńlá rẹ̀gẹ̀jì kan báyìí ni wọ́n gbéra, wọ́n sì tọ ipasẹ̀ rẹ̀ dí abẹ́ igi náà
  9. Bí wọ́n ṣe dé abẹ́ igi náà ni ẹyẹlé yìí tún fò, tó sì balẹ̀ tepọ́n sí ibi ẹsẹ̀ Mọrèmi
  10. Ọ̀tún Ọ̀délé mú ẹyẹ yìí, ó nà án sókè lójú ọ̀run, ó sì fi í wúre fún ìlú tuntun tí Mọrèmi ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ dá sílẹ̀ pé kó tùbà-tùṣẹ, pé kí ó rójú, kí ó sì tura fún àwọn olùgbé ibẹ̀
  11. Lẹ́yìn ìwúre yìí Ọ̀tún yọ ọ̀bẹ tuntun kan jáde, ó sì pa ẹyẹlé náà, ó là á láyà, ó da epo, iyọ̀ àti oyin lé e
  12. Ó wá fi wọ́n sọ gbólóhùn ìwúre mẹ́ta pé yóò dẹ̀ wọ́n lọ́rùn pẹ̀sẹ̀; pé ayé wọn ò níí dòbu àti pé adùn bí oyin kò ní kúrò lọ́rọ̀ ayé wọn
  13. Lẹ́yìn tí ó ti ṣe gbogbo aájò yìí tán, Ọ̀tún wa ilẹ̀ sí ibi tí òun, Mọrèmi àti Ọlálọmí dúró sí, ó sì ri ẹyẹ náà mọ́lẹ̀
  14. Orúkọ tí Mọrèmi fún ìlú náà ni Ìlú Mọrèmi
  15. Báyìí ni wọ́n ṣe dá Ìlú Mọrèmi sílẹ̀

Most candidates who read the text captured the narrative very well and scored good marks.