Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2023

Question 4

 

a. Fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ìwọ̀nyí ní oríkì:

i.  gbólóhùn oníbọ̀

ii. olórí awẹ́ gbólóhùn

iii. awẹ́ gbólóhùn afarahẹ

 

(b)     Fa olórí awẹ́ gbólóhùn inú ọ̀kọ̀ọ̀kan gbólóhùn wọ̀nyí yọ

i. Ọ̀gá tí ó fẹ́ràn mi ti dé.

ii. Ó dá mí lójú pé Ọlọ́run ń bẹ.

iii. Gbogbo wọn ti lọ kí a tóó dé.

iv. Ìbáà lówó, kò lè jọba.

v. Bí mo bá lówó, màá kọ́lé.

vii. Ẹ jẹun kí ẹ tóó lọ.

 

Observation

 

Candidates were tasked to define a complex sentence in a(i), a main clause in a(ii), a surbordinate clause in a(iii) and identify the main clauses in the given sentences in b.

4.       (a) Oríkì àwọn wúnrẹ̀n:
(i)      Gbólóhùn Oníbọ̀: Èyí ni gbólóhùn tí a ti fi gbólóhùn kan há (ìhun) òmíràn.
(ii)      Olórí awẹ́ gbólóhùn: Èyí ni apá kan tí ó lè dá dúró nínú gbólóhùn oníbọ̀
(iii)     Awẹ́-gbólóhùn afarahẹ: Èyí ni apá kan tí kò lè dá dúró láìfi ara ti olórí awẹ́-gbólóhùn nínú gbólóhùn oníbọ̀

          (b)     Àfàyọ olórí awẹ́-gbólóhùn:


S/N

GBÓLÓHÙN

ÀFÀYỌ OLÓRÍ AWẸ́-GBÓLÓHÙN

(i)

Ọ̀gá tí ó fẹ́ràn mí ti dé

Ọ̀gá ti dé

(ii)

Ó dá mi lójú pé Ọlọ́run ń bẹ

Ó dá mi lójú

(iii)

Gbogbo wọn ti lọ kí a tóó dé

Gbogbo wọn ti lọ

(iv)

Ìbáà lówó kò lè jọba

Kò lè jọba

(v)

Bí mo bá lọwọ màá kọ́lé

Màá kọ́lé

(vi)

Ẹ jẹun kí ẹ tóó lọ

Ẹ jẹun

Most candidates missed out on the definitions but perfomed well in the identification of the main clause.