Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2022

Question 11

Irú ẹ̀dá ìtàn wo ni Bọ̀sípò jẹ́?

 

Observation

Candidates were tasked to describe the personality of Bosipo, a character in the drama text.

Irú ẹ̀dá ìtàn tí Bọ̀sípò jẹ́:

  1. Bọ̀sípò jẹ́ ọmọ tí Àdíjá bí fún Ọládẹ̀jọ
  2. Ọmọ olówó ni Bọ̀sípò, àwọn òbí rẹ̀ sì rówó kẹ́ ẹ
  3. Àwọn òbí rẹ̀ rán an lọ sí ilé-ẹ̀kọ́
  4. Àkẹ́bàjẹ́ ni Bọ̀sípò, àwọn òbí rẹ̀ kì í jẹ́ kí ó ṣiṣẹ́ ilé kankan/kò mọ iṣẹ́ ilé kankan ṣe
  5. Bọ̀sípò fẹ́ràn láti máa wo fíìmù dípò kí ó máa kàwé
  6. Olódo tí kò fẹ́ràn maths (ìṣirò) ni Bssípò jẹ́, Oyèládùn ni ó máa ń bá ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá maths rẹ̀
  7. Bọ̀sípò gọ̀ ju iṣu lọ
  8. Ọ̀lẹdàrùn ni Bọ̀sípò, ó máa ń parọ́ pé ara òun kò yá bí kò bá ti ṣe homework rẹ̀, kò ní lọ sí ilé ẹ̀kọ́
  9. Olè ni Bọ̀sípò, ó máa ń jí owó àwọn òbí rẹ̀ tí wọ́n gbàgbé rẹ̀ sílẹ̀
  10. Olójú àánú ni Bọ̀sípò, ó fún oyèládùn ní náírà méjì owó takisí nígbà tí Oyèládùn fẹ́ fẹsẹ̀ rìn lọ sí ilé wọn láti ta bàbá rẹ̀ lólobó lórí ohun tí ó gbọ́ sí i
  11. Òpùrọ́ ni Bọ̀sípò, ó purọ́ fún bàbá rẹ̀ pé kì í ṣe ọwọ́ òun ni fídíò ti bàjẹ́, bẹ́ẹ̀ òun ni ó mú ọ̀rẹ́ wálé tí wọ́n jọ fi fídíò wo fíìmù Bruce Lee tí fídíò fi bàjẹ́ mọ́ wọn lọ́wọ́

 

 

Candidates’ performance in this question was satisfactory.