Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2023

Question 8

 

Kí ni ó fàá tó fi jẹ́ pé òru nìkan ni Orò ń jáde?

Observation


 Candidates were required to explain the origin of Orò’s nightly appearance as narrated in the text.

 

Ohun tí ó fà á tó fi jẹ́ pé òru nìkan ni Orò ń jáde:
(i)      Òrìṣà ni Egúngún àti Oró ni ilẹ̀ Yorùbá
(ii)      Ìtàn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìbejì ni àwọn méjèèjì  
(iii)     Orò lẹ̀gbọ́n, Egúngún làbúrò
(iv)     Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni àwọn méjèèjì ń ṣe
(v)      Ìyàwó wọn ni ó sì ń ta irè oko wọn lọ́dọọdún
(vi)     Ìyàwó Egúngún ń fi owó díẹ̀díẹ̀ pamọ́, ó sì ń raṣọfún ọkọ rẹ̀
(vii)    Onínà-án-kúnà-án obìnrin ni ìyàwó Orò, tìfun-lọ̀ràn ni, kì í rí owó fi pamọ́
(viii)   Ìyàwó Orò kì í raṣọ fún ọkọ rẹ̀
(ix)     Ní ọjọ́ kan, Egúngún àti Orò fẹ́ẹ́ lọ sí òde
(x)      Egúngún kò sínú aṣọ tí ó jíire ṣùgbọ́n Orò kò rí aṣọ gidi kan wọ̀n
(xi)     Èyí mú kí Orò rí àṣìṣe aya rẹ̀
(xii)    Orò mú àtòrì rọ̀jọ̀rọ̀jọ̀, ó kó o bo ìyàwó rẹ̀
(xiii)   Ìyàwó Orò sá, ó korí bọ igbó
(xiv)   Orò lé e kò bá a nítorí pé ìhòhò ni Orò wà
(xv)    Láti ìgbà náà ni Orò ti ń pe Ìyàwó yìí kágbó tí ó sì máa ń sọ pé ‘Bun-un-bun-un-bun-un’
(xvi)   Egúngún a máa jáde láàárọ̀, lọ́sàn-án tàbí lálẹ́ nítorí aṣọ tí ó jíire ni ó máa ń wọ̀ sọ́rùn.
(xvii)   Òru nìkan ni Orò fi ń rìn jáde nítorí ipò oníhòòhò tí ó máa ń wà
(xviii)  Ìdí nìyí tí Orò fi máa ń jáde ní òru nìkan.
Candidates are required to mention the specific speech art of Ẹ̀gè Dídá.

 

The question was fairly tackled by those who read the text.