Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2023

Question 6

 

Báwo ni ó ṣe di pé wọ́n wá ń fi Ìjàpá bọ Ọ̀sányìn gẹ́gẹ́ bí ó ṣe hàn nínú ìtàn “Ìjàpá lóyún Ìjàngbọ̀n”?

Observation


Candidates were tasked to narrate how Ìjàpá became an object of sacrifice for Ọ̀sányìn as evident in the folk tale.

Bí ó ṣe di pé wọ́n wá ń fi Ìjàpá bọ Ọ̀sányìn:
(i)      Ìjàpá àti aya rẹ̀ Yánníbo ṣe ìgbéyàwó
(ii)      Inú Yánníbo kò dùn tó bẹ́ẹ̀ nítorí pé kò lóyún àárọ̀ dalẹ́ rí
(iii)     Nígbà tí ó pé ogún ọdún tí Yánníbo kò rí ọmọ bí, ó pe ọkọ rẹ̀, ó rọ̀ ọ́ pé kí ó má jẹ́ kí agara dá àwọn lórí aájò à-ń-wọ́mọ
(iv)     Ìjàpá, ọkọ rẹ̀, ṣèlérí láti lọ ṣaájò lọ́dọ̀ Àkàlà, babaláwo, tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ Ìjàpá
(v)      Ìjàpá tọ Àkàlà lọ láti ṣe aájò àtirọ́mọbí ìyàwó rẹ̀, Àkàlà sọ fún Ìjàpá pé àìfi ọ̀rọ̀ náà lọ òun ni kò jẹ́ kí òun bá wọn dá sí i
(vi)     Àkàlà ṣèlérí pé òun yóò sa ipá òun tí Yánníbo yóò fi lóyún ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ èèwọ̀ òògùn tí òun yóò ṣe fún Yánníbo fún Ìjàpá
(vii)    Àkàlà kìlọ̀ fún Ìjàpá pé kò gbọdọ̀ tọ́ wó nínú àsèjẹ tí òun bá ṣe fún Yánníbo
(viii)   Bí Ìjàpá ti dé láti wá gba àsèjẹ fún Yánníbo, Babaláwo tún kìlọ̀ fún un pé kò gbọdọ̀ tọ́ wò nínú àsèjẹ náà nítorí pé bí ó bá dan wo ikú ni ẹ̀rọ̀ rẹ̀
(ix)     Bí Ìjàpá ti ń padà lọ sí ilé pẹ̀lú àsèjẹ Yanníbo, ọbẹ̀ yìí ń ta sánsán sí i nímú, ó ń fi imú fa òórùn rẹ̀
(x)      Ìjàpá dúró, ó ṣí ọbẹ̀ náà wò, ọbẹ̀ àti ẹja àrọ̀ tí ó wà nínú rẹ̀ wọ̀ ọ́ lójú, ó fẹ́ mú jẹ níbẹ̀ ṣùgbọ́n bí ó ti rántí ìkìlọ̀ ni ó de padà
(xi)     Nígbà tí ara Ìjàpá kò gbà á mọ́, ó mú ìrù ẹja pùkẹ́pùkẹ́ kan, ó sọ ọ́ sẹ́nu, ó sì ń jẹ ẹ́ ní àjẹrìn
(xii)    Ẹja yìí dùn mọ́ ọn lẹ́nu, ó wá gbé àsèjẹ náà kalẹ̀ nídìí igi kan, ó sì jẹ gbogbo rẹ̀ tán kí ó tó wáá fọ́ ìkòkò àsèjẹ náà mọ́lẹ̀
(xiii)   Bí Ìjàpá ṣe jẹ àsèjẹ náà tán, ó ń lọ sílé, ó pinnu pé òun yóò purọ́ fún Yánníbo pé Àkàlà kòì ṣe àsèjẹ rẹ̀
(xiv)   Bí ó ti ń lọ lọ́nà ni inú rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ síí wú, ó ń ga, ó ń fẹ̀, ó sì ń tóbi sí i
(xv)    Ìjàpá kò lè rìn dáadáa mọ́, ó wá ń kérora
(xvi)   Nígba tí inú rẹ̀ fẹ́ẹ́ bẹ́, ó ṣẹ́rí padà láti lọ bẹ Àkàlà pé kí ó bá òun rọ kiní náà
(xvii)  Bí Ìjàpá ti rí ilé Àkàlà lọ́ọ̀ọ́kán ni ó forin sẹ́nu, tí ó ń kọ ọ́ tàánútàánú pé:
Lílé: Bàbaláwo mò wá bẹ̀bẹ̀
                             Ègbè: Alugbinrin
(xviii)  Àkàlà jẹ́ kí Ìjàpá mọ̀ pé kò sí ẹ̀rọ̀ fún un àti pé ikú ni ẹ̀rọ̀ rẹ̀
(xix)   Nígbà tí ẹ̀bẹ̀ pọ́, Àkàlà ní kó lọ sójú Ọ̀sányìn kí ó lọ bẹ̀ ẹ́ nítorí pé Ọ̀sányìn ni Òrìṣà ìṣẹ́gunbóya yóò lè rí ìwòsàn lọ́dọ̀ rẹ̀
(xx)    Ìjàpá fi ìdí wọ́ dé ojú Ọ̀sányìn, ó dọ̀bálẹ̀, ó ń bẹ̀bẹ̀
(xxi)   Ọ̀sányìn ní ó ti jèèwọ àti pé ẹ̀mí rẹ̀ ni yóò fi ṣètùtù
(xxii)  Ìgbà tí inú Ìjàpá tóbi tí tí tí , ló bá bẹ́ pòó sóju Òrìṣà Ọ̀sányìn, ni Ọ̀sányìn bá gbé Ìjàpá, ó jẹ ẹ́
(xxiii)  Láti ìgbà yìí ni ó di pé wọ́n wá ń fi Ìjàpá bọ Ọ̀sányìn

 

Candidates who attempted this quuestion did justice to it.