Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2023

Question 13

eẹ̀kùnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí àwọn ohun tí a lè rí lára igi ọ̀pẹ

Observation

Candidates were required to give detailed explanation on materials that can be derived from the palm tree.

Àlàyé lórí àwọn ohun tí a lè rí lára igi ọ̀pẹ:
(i)      Oje ọ̀pẹ tí wọ́n ń dá ni à ń pé ní ẹmu
(ii)      Oodi ẹyìn tí a rí lára ọ̀pẹ ni a fi ń ṣe epo pupa
(iii)     Imọ̀ ọ̀pẹ ni àwọn kan fi ń kọ́lé
(iv)     Èkùrọ́ inú ẹyìn la fi ń ṣe àdí
(v)      Èèpo èkùrọ́ ni eésan tí àwọn alágbẹ̀dẹ fi ń dáná nílé arọ́ àti nínú ilé
(vi)     Ẹfọ́n ọ̀pẹ ni wọ́n fi ń hun apẹ̀rẹ̀/agbọ̀n, kùùkú adìẹ
(vii)    À ń rí ọwọ̀ tí a fi ń gbálẹ̀ lára ọ̀pẹ
(viii)   Ihá ọ̀pẹ ni a fi ń dáná
(ix)     Màrìwò ọ̀pẹ ni wọ́n fi ń ta jaala sí lé Ògún
(x)      Igi ọ̀pẹ ni wọ́n ń là sí paakun tí à ń lò bí igi ìrólé
(xi)     Ọ̀wá ọ̀pẹ ni àwọn ọmọdé fi máa ń ṣe eré ṣìbáláṣìbo
(xii)    Ògùṣọ ara ọ̀pẹ tí a sá tó gbẹ là ń lò fún iná dídá
(xiii)   Àran gbígbẹ spẹ ni à ń tà ní àtijọ láti fi dáná kó lè tètè jó
tí ó jẹ̀ alágbẹ̀dẹ ọ̀run
(xiv)   Iháhá ọ̀pẹ ni a fi ń ṣe kànhìn-kànhìn tí a fi ń fọ abọ́ àti agbẹ̀ ẹmu.

Many candidates attempted this question and they performed brilliantly well.


 
Untitled Document