Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2020

Question 4

 

Kọ àwọn ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ wọ̀nyí sílẹ̀ kí o sì lo ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn nínú gbólóhùn:
(a) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹyọ ẹnikínní ní ipò olùwà;
(b) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ọ̀pọ̀ ẹnìkejì ní ipò àbọ̀;
(d) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹyọ ẹnìkejì ní ipò olùwà;
(e) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ọ̀pọ̀ ẹnikẹta ní ipò àbọ̀;
(ẹ) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹyọ ẹnikínní ní ipò ẹ̀yán.


In answering this question, candidates were expected to provide the words depicting described pronouns and give appropriate illustrative sentence for each of the given pronouns.

(a)      Àwọn ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ
i. mo/mò/N
ii. yín
iii. o
iv. wọn/wọ́n
v. mi

 

 (b)     Ìlò ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn nínú gbólóhùn                     
(i)  Mo/mò/N – Mo ti dé/ Mò ń jẹun/N kò fẹ́ ìyẹn/N óò dé lọ́la.
(ii)      Yín/ – Bọ́lá rí yín/Bàbá ń pè yín.                               
(iii)     O – O ti lọ/O ti fún mi/O káre.                                 
(iv)     wọn/wọ́n – Délé rí wọn/Bàbá pè wọ́n.                      
(v)      Mi – Aṣọ mi mọ́ tónítóní/Ìwé mi dà?                                   
Most candidates were able to correctly answer this question. However, more work is expected to be done in the teaching of this particular topic.