Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2020

Question 13

 

Ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ tí ọmọ-ọdẹ máa ń kọ́ níbi ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọdẹ.


Candidates were required to describe the skills that a prospective hunter is expected to acquire in order to become a master hunter.

Àwọn ẹ̀kọ́ tí ọmọ-ọdẹ máa ń kọ́ níbi ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọdẹ:

  1. Yóò kọ́ nípa lílo onírúurú irinṣẹ́ ọdẹ.
  2. Yóò kọ́ bí a ti ń fi ojú sun ẹran tí ìbọn, ọfà tàbí àkàtàǹpó kò fi níí tàsée rẹ̀
  3. Yóò kọ́ bí a ṣe ń gẹ̀gùn àti bí a ṣe ń lúgọ de ẹranko tí a fẹ́ẹ́ pa.
  4. Yóò kọ́ bí a ṣe ń mọ̀ pé ẹranko ń bọ̀ láti apá ibì kan.
  5. Yóò kọ́ bí a ṣe ń rìn nínú igbó tí a kò fi níí lé ẹran lọ.
  6. Yóò kọ́ bí a ṣe ń yin ìbọn tí kò níí ba ọdẹ mìíràn tí wọn jọ lọ sí ìgbẹ́.
  7. Yóò kọ́ nípa ọ̀gangan ibi tí a máa ń yin ìbọn sí ní ara ẹran tí yóò fi lè pa á ní àpafọ̀n tí ẹran náà kò fi níí gbé ọgbẹ́ ìbọn sá lọ/fi ẹ̀tù ṣòfò.
  8. Yóò kọ́ bí ọdẹ ṣe ní láti máa sọ̀rọ̀ nínú igbó, kí ẹranko má bàá gbọ́ ohùn ọdẹ kí ó sì sá lọ.
  9. Ó ní láti kọ́ nípa ètùtù ṣíṣe fún ẹranko abàmì tí ó bá pa.
  10. Yóò kọ́ nípa àwọn èèwọ̀ ọdẹ.
  11. Ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọdẹ gbọ́dọ̀ kọ́ ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni, ìgboyà, ìlawọ́, ìforítì, sùúrù àti ìjáfáfá.
  12. Yóò kọ́ nípa oríṣiríṣi oògùn tí ọdẹ fi ń ṣe agbára.
  13. Yóò kọ́ nípa àwọn igbó àìwọ̀ tí ó wà ní àrọ́wọ́tó.
  14. Yóò kọ́ bí a ṣe ń bọ̀wọ̀ fún àwọn àgbà ọdẹ.
  15. Yóò kọ́ bí a ṣe ń bọ Ògún.
  16. Yóò kọ́ bí a ṣe ń ní ìfura.
  17. Yóò kọ bí a ṣe ń lo ajá láti dẹ ìgbẹ́.
  18. Yóò kọ́ bí a ṣe ń dẹ pàkúté/pan̄pẹ́/gbóró, ìrín, ọṣọ́, ìgèrè, abbl.
  19. Yóò kọ́ bí a ṣe ń kun ẹran.

The answers given revealed a shallow knowledge of the subject matter. Candidates who attempted this question performed poorly.