Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2020

Question 10

 

Nínú ewì “Afún-n-ṣọ́”, àwọn ọ̀nà wo ni akéwì sọ pé kò dára láti máa lo ọmọ?


Candidates were required to present the author’s recommendations for parents while scolding their erring children.

Akéwì sọ pé:

  1. Àṣìlò ọmọ ni ká fọmọ ṣe ọmọ-ọ̀dọ̀
  2. Kò dára ká jẹ́ kí ọmọ máa pọn omi tà
  3. Iṣẹ́ agbèrò kò yẹ màjèṣí
  4. Ìwà ọ̀daràn ni ká máa lu ọmọ nílùu bàrà
  5. Kò dára ká máa bọ́mọ wí tìkanratìkanra
  6. Kí a máa bínú lu ọmọ jẹ́ ìwà ìkà
  7. Ká máa yọ àpólà igi láti lu ọmọ, ẹ̀ṣẹ̀ ni
  8. Kò sunwọ̀n ká máa gbọ́mọ létí, máa gé ọmọ jẹ
  9. Kò wuyì ká máa fi ìgbálẹ̀ lu ọmọ
  10. Kò bójú mu ká máa fi àkúfọ́ ìgò ya ọmọ lára
  11. Kò dára kí abiyamọ le mọ́ ọmọ jù.
  12. Kí á máa fi ọmọrogùn lu ọmọ kò dára.
  13. Kí a máa ju òkò, abọ́, igi lu ọmọ láti bá a wí kò dára

 

This question was poorly answered by most candidates who, obviously, did not study the prescribed text. General guesses based on societal knowledge were made.