Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2020

Question 12

 

Mẹ́nu ba ohun mẹ́fà tí o mọ̀ nípa Ọ̀rúnmìlà bí ó ṣe hàn nínú ẹ̀sìn ìbílẹ̀ Yorùbá


Candidates were required to mention six attributes of Ọ̀rúnmìlà.

Àwọn ohun mẹ́fà nípa Ọ̀rúnmìlà bí ó ṣe hàn nínú ẹ̀sìn ìbílẹ̀ Yorùbá: 
(i)      Ọ̀kan nínú àwọn àgbà irúnmọlẹ̀/òrìṣà/ìbọ ni Ọ̀rúnmìlà.
(ii)      Ọkùnrin ni Ọ̀rúnmìlà
(iii)     Ọlọgbọ́n ni Ọ̀rúnmìlà/Akéréfinúṣọgbọ́n ni.
(iv)     Nígbà ayé rẹ̀, ènìyàn kúkúrú dúdú ni/Ọkùnrin kúkúrú Òkè Ìgẹ̀tí
(v)      Òun ni ó dá ifá dídá/àyẹ̀wò ṣíṣe sílẹ̀
(vi)     Lára àwọn ohun tí Ọ̀rúnmìlà fi ń dá Ifá ni ọ̀pẹ̀lẹ̀, ikin, ìyẹ̀ròsùn, ọpọ́n-ifá, ìrọ́kẹ́    àti àwọn ohun ìdìbò bíi egungun, òkúta dídán, owó-ẹyọ, abbl.
(vii)    Gbáyé-gbọ́run ni Ọ̀rúnmìlà.
(viii)   Lára ohun tí wọ́n fi ń bọ Ọ̀rúnmìlà ni eku, ẹja, ewúrẹ́, obì, adìyẹ àti ọtí
(ix)     Ó máa ń sun ìyẹ̀rẹ̀
(x)      Àwọn ìlù tí wọ́n máa ń lù fún Ọ̀rúnmìlà ni agogo, àràn àti ọ̀pá.
(xi)     Òpìtàn Ifẹ̀ ni Ọ̀rúnmìlà
(xii)    Ọ̀rúnmìlà ni Ẹlẹ́rìí-ìpín./ Ó wà níbẹ̀ nígbà tí ẹni kọ̀ọ̀kan ń yan ìpín rẹ̀ ní ọ̀run.
(xiii)   Ọ̀rúnmìlà ni Olódùmarè rán wá sí ayé láti wáá tún orí tí kò sunwọ̀n ṣe.
(xiv)   Gbogbo òrìṣà pátá ni Ọ̀rúnmìlà mọ àtiwáyé wọn.
(xv)    Ọ̀rúnmìlà kò ní egungun lára láti fi ṣe iṣẹ́ agbára.

This question was poorly tackled by most candidates, revealing an inadequate knowledge of the subject matter. More work should be done by the teachers in teaching the students the topics under Yorùbá beliefs, customs and institutions.