v Yoruba Paper 2, Jan - Feb 2021


Yoruba Paper 2 WASSCE (PC), 2021

Question 12

 

 

Ṣe àlàyé ohun tí àwọn wọ̀nyí jẹ́ nínú ayò títa:
(a)      ọmọ-ayò;
(b)     òdù.

Observation

 

 

Candidates were required to describe the terms in a Yoruba traditional game “Ayò-títa”.

                    (a)      Ọmọ-ayò:


(i)      Igi eléso kan báyìí tí ó ni èso tí ó ń dán ni ó ń pèsè ọmọ-ayò
(ii)      Ọmọ-ayò yìí ni a máa ń lé sí ojúlé ọpọ́n-ayò
(iii)     Ojúlé méjìlà (mẹ́fà ní apa ọ̀tún, mẹ́fà ní apá òsì) ni ọpọ́n-ayò máa ń ní
(iv)     Ọmọ-ayò mẹ́rin mẹ́rin ni à ń lé sínú ojúlé ọpọ̀n-ayò kọ̀ọ̀kan
(v)      Ọmọ-ayò yìí ni àwọn ọ̀tayò máa ń ta, tí wọ́n máa ń jẹ/kó tí kò bá ju méjì tàbí mẹ́ta lọ níbi tí ó parí sí; apá ọ̀tún ni wọ́n máa ń ta á sí
(vi)     Bí kò bá sí ọmọ-ayò ní àrọ́wọ́tó, a máa ń lo kóró iṣin tàbí òkúta akọ wẹ́wẹ́ tó ń dán.


(b)     Òdù:


(i)      Àwọn ọ̀tayò tó já fáfá ni ó máa ń kún òdù
(ii)      Kíkún òdù ni pé kíkó ọmọ-ayò jọ sójúlé ayò kan ní ọ̀dọ̀ ẹni
(iii)     Bí a ti ń kún òdù ni a ó máa kà á kí ó má báa fò, kí ó má sì forí ṣọ́npọ́n
(iv)     Àwọn ọmọ-ayò tí a kó jọ yìí lè yí ojúlé-ayò tí ó wà lójú ọpọ́n ayò po lẹ́ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀mejì
(v)      Bí òdù kò bá jẹ, ó forí ṣọ́pọ́n nìyẹn
(vi)     Bí òdù bá yíká ilé àwọn òǹtayò méjèèjì tí ó sì padà wá sí ilé ẹni tí ó kún òdù náà, á jẹ́ pé òdù náà fò/tàbí pé ó jù nìyẹn
(vii)    Òǹtayò kò lè fi òdù jẹ ayò ju ihò méjì, mẹ́ta, mẹ́rin tàbí márùn-ún lọ


Candidates who attempted this question performed fairly well.