v Yoruba Paper 2, Jan - Feb 2021


Yoruba Paper 2 WASSCE (PC), 2021

Question 10

 

 

Àwọn èèwọ̀ wo ni akéwì mẹ́nu bà nínú ewì rẹ̀ “Èèwọ̀ ni”

Observation

 

 

Candidates were required to recall various taboos mentioned by the poet evident in the poem “Èèwọ̀ ni”

  1. Rìbá gbígbà àti owó kíkójẹ jẹ́ èèwọ fún oníṣẹ́ ọba
  2. Ojo ṣíṣe lẹ́nu iṣẹ́ fún àwọn akéwì jẹ́ èèwọ̀
  3. Àwọn olórin kò gbọ́dọ̀ kọrin ọ̀fẹ́
  4. Agbẹjọ́rò kò gbọdọ̀ ṣèrú tàbí kó dalẹ̀ oníbàárà rẹ̀
  5. Adájọ́ kò gbọdọ̀ gba rìbá
  6. Onílé kò gbọdọ̀ fi ara ni ayálégbé
  7. Olùkọ́ kò gbọdọ̀ bá akẹ́kọ̀ọ́ lò pọ̀
  8. Dókítà kò gbọdọ̀ tú àṣị́rí aláìsàn
  9. Nọ́ọ̀sì kò gbọdọ̀ kó oògùn tàbí àpò-ẹ̀fọn ilé-ìwòsàn tà
  10. Atọ́kọ̀ṣe kò gbọdọ̀ ra ayédèrú ẹ̀yà-ara ọkọ̀ fún oníbàárà rẹ̀
  11. Ènìyàn kò gbọdọ̀ jẹ ọ̀gà
  12. Ènìyàn kò gbọ̀dọ̀ jẹ dágunró
  13. Ènìyàn kò gbọdọ̀ jẹ gùdùgúdú
  14. Ènìyàn kò gbọdọ̀ jẹ igún
  15. Ajá kò gbọdọ̀ jẹ ìfun òkété
  16. Ìgbàgbọ́ kì í jẹ ọ̀pọ̀lọ́
  17. Mùsùlùmí kò gbọdọ̀ jẹ ajá
  18. A kì í kí ọba lóòró
  19. A kì í fi ẹni kúkúrú ṣe awo ẹni tó gùn.

Candidates’ performance was poor, general guesses were made and not as evident in the text.