Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2022

Question 2

 

(a)  Kí ni ibi ìṣẹnupè ?      
(b)  Fi ibi ìṣẹnupè ṣe àlàyé àwọn kọ́ńsónáǹtì tí ó wà nínú gbólóhùn yìí: Mo ka ìwé fún iṣẹ́ yìí.

Observation

 

Candidates were required to define the place of articulation in (a) and identify the consonants in the given sentence and mention the place of articulation for each of the identified consonants in (b)
Oríkì ibi ìṣẹnupè       
Ibi ìṣẹnupè ni ó  máa ń tọ́ka sí ọ̀gangan ibi tí a ti pe àwọn ìró kọ́ńsónáǹtì. Ó máa ń tọ́ka sí irú àwọn afipè tí a lò (àsúnsí àti àkànmọ́lẹ̀).
                                                                                                                                                         
(b) b(i) Àwọn kọ́ńsónáǹtì tí ó wà nínú gbólóhùn “Mo ka ìwé fún iṣẹ́ yìí”: m, k, w, f, ṣ àti y. 

 

b(ii)    Àlàyé lórí ibi ìṣẹnupè  kọ́ńsónáǹtì kọ̀ọ̀kan


S/N

Kọ́ńsónáǹtì

Àlàyé ibi ìṣẹnupè rẹ̀

1

m

Ètè méjèèjì ni a fi pe kọ́ńsónáǹtì m (ètè ìsàlẹ̀ ni afipè àsúnsí; ètè òkè ni afipè àkànmọ́lẹ̀)

2

k

Ẹ̀yìn-ahọ́n àti àfàsé ni a fi pe kọ́ńsónáǹtì k (ẹ̀yìn ahọ́n ni afipè àsúnsí; àfàsé ni afipè àkànmọ́lẹ̀)

3

w

Ètè méjèèjì pẹ̀lú ẹ̀yìn-ahọ́n àti àfàsé ní ẹ̀ẹ̀kan náà ni a fi pe kọ́ńsónáǹtì w (ètè ìsàlẹ̀ àti ẹ̀yìn-ahọ́n ni afipè àsúnsí; ètè-òkè àti àfàsé ni afipè àkànmọ́lẹ̀)

4

f

Ètè-ìsàlẹ̀ àti eyín-òkè ni a fi pe kọ́ńsónáǹtì f (ètè-ìsàlẹ̀ ni afipè àsúnsí; eyín-òkè ni afipè àkànmọ́lẹ̀)

5

Iwájú-ahọ́n pẹ̀lú ibi tí ó wà láàrin àjà-ẹnu àti èrìgì ni a fi pe kọ́ńsónáǹtì (iwájú-ahọ́n ni afipè àsúnsí; ibi tí ó wà ní ààrin àjà-ẹnu àti èrìgì ni afipè àkànmọ́lẹ̀)

6

y

Ààrin-ahọ́n àti àjà-ẹnu ni a fi pe kọ́ńsónáǹtì y (Ààrin-ahọ́n ni afipè àsúnsí; àjà-ẹnu ni afipè àkànmọ́lẹ̀)

 

Many of the candidates who attempted this question performed fairly well as they could only define the place of articulation and identify the consonants in the given sentence but failed to mention the correct places of articulation for each consonant.