Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2022

Question 13

Ṣe àpèjúwe ayò títa gẹ́gẹ́ bí eré ìdárayá láàrín àwọn Yorùbá

Observation

Àpèjúwe ayò títa gẹ́gẹ́ bí eré ìdárayá kan láàrin àwọn Yorùbá

  1. Ọ̀kan lára àwọn eré ìdárayá ìbílẹ̀ Yorùbá ni ayò títa jẹ́
  2. Nígbà tí ọwọ́ bá dilẹ̀ ni a máa ń ta ayò
  3. Tọmọdé tàgbà, tọkùnrin tobìnrin, ló ń ta ayò
  4. Ọpọ́n ayò àti ọmọ ayò ni ohun-èlò tí a fi ń ta ayò
  5. Ọpọ́n ayò ni igi tí a gbẹ́ tí ó ní ihò méjìlá; mẹ́fà mẹ́fà ní apá kọ̀ọ̀kan
  6. Ọmọ ayò ni èso igi tí a ṣà jọ, a tún máa ń lo kóró iṣin tàbí òkúta wẹ́wẹ́ tó ń dán
  7. Ọmọ ayò mẹ́rin mẹ́rin ni a máa ń kó sí ojúle kọ̀ọ̀kan nínú ọpọ́n ayò
  8. Ọmọ ayò méjìdínláàdọ́ta yóò pé sí inú ọpọ́n ayò kí a tóó lè bẹ̀rẹ̀ ayò títa 
  9. Lára òfin eré ayò ni pé ènìyàn méjì péré ni ó máa ń ta ayò lẹ́ẹ̀kan náà ní ìkọjú síraa wọn
  10. Láti apá òsì sí apá ọ̀tún ni a máa ń ta ayò
  11. Ọ̀tayò kì í jẹ ayò nínú “ilé” ara rẹ̀
  12. Ọ̀ta ni a máa ń pe ẹni tí ó bá pa ẹni tó ń bá tayò lẹ́ẹ̀mẹta léraléra 
  13. Ọ̀tayò tí a pa ní mẹ́ta léraléra ni Òpè
  14. Ọ̀tayò kò lè jẹ ju ọmọ ayò méjì tàbí mẹ́ta lọ nínú ihò kan
  15. Ọ̀tayò lè kún òdù
  16. Òdù tí kò bá jẹ ni a máa ń sọ pé “ó fò tàbí ó jù”
  17. Ọ̀tayò tí ó bá jẹ ọmọ ayò tí ó lé ní mẹ́rìnlélógún ni ó pa
  18. Tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀tayò méjèèjì bá jẹ mẹ́rìnlélógún, ọ̀mì ni wọ́n ta yẹn
  19. “Mo kí ọ̀ta, mo kí òpè” ni a máa ń kí àwọn ọ̀tayò
  20. Ìdáhùn ìkíni yìí ni “Ọ̀ta ń jẹ́, òpè ni kò gbọdọ̀ fọhùn”
  21. Wọn kì í sábà jà ní ìdí eré ayò nítorí  pé “Eré ni à ń fi ọmọ ayò ṣe”
  22. Àǹfààní láti ṣe àwàdà àti láti sọ ọ̀rọ̀ apanilẹ́rìn-ín wà fún àwọn ọ̀tayò àti èrò ìwòran
  23. Ayò títa máa ń kọ́ni lọ́gbọ́n
  24. máa ń wáyé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan níbi ayò títa Òjóóró

Candidates who attempted this question tackled it well.


 
Untitled Document