Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2022

Question 6

 

Báwo ni Ìjàpá ṣe dé ibi ìkómọjáde àrẹ̀mọ Àdán nínú ìtàn “Ìjàpá lọ jẹ àsè ní ilé Àdán”

Observation


Candidates were required to narrate the story of how Ìjàpá, a character in the folktale deceitfully went to feast in Àdán’s house during the name giving ceremony of his son in the folktale, “Ìjàpá lọ jẹ àsè ní ilé Àdán”.

Ìjàpá ṣe dé ibi ìkómọjáde àrẹ̀mọ Àdán:
(i)         Ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ ni Ìjàpá àti Àdán
(ii)        Àdán máa ń wá jẹ àsè ní ilé Ìjàpá nígba tí Ìjàpá bá ní ṣíṣe 
(iii)       Ìjàpá kò ní àǹfààní láti lọ máa jẹ àsè ní ilé Àdán nítorí pé kò lè dé orí igi gíga tí Àdán ń gbé, kò le gungi, kò sì lè fò
(iv)       Ìbànújẹ́ ńlá ni èyí jẹ́ fún Ìjàpá nítorí pé gbogbo ìgbà tí Àdán bá ti ní ṣíṣe ni Ìjàpá máa ń fún un ní ẹ̀bùn tí kì í sì ní àǹfààní láti jẹ nínú àsè náà
(v)        Ìjàpá rèé, ó fẹ́ràn oúnjẹ, ó wáá pinnu láti dọ́gbọ́n sí ọ̀rọ̀ náà nígbà tí Àdán bá tún ní ṣíṣe 
(vi)       Ọmọ mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ tí Àdán kọ́kọ́ bí jẹ́ obìnrin
(vii)      Ọmọ kẹsàn-án tí Àdán bí ní àsìkò yìí jẹ́ ọkùnrin
(viii)     Inú Àdán dùn, gbogbo ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ sì bá a yọ ayọ̀ ọmọ tuntun yìí
(ix)       Àdán ń palẹ̀ mọ́ fún ìkómọjáde, kálukú sì ń fún un ní ẹ̀bùn bí ipá wọn ti tó
(x)        Ìjàpá pinnu nínú ọkàn rẹ̀ pé òun gbọ́dọ̀ wà níbi ìkómọ ọmọ Àdán
(xi)       Ìjàpá sọ èrò rẹ̀ fún Yánníbo, aya rẹ̀.
(xii)      Yánníbo béèrè ọnà tí èyí yóò gbà ṣeé ṣe nígbà tí ọkọ rẹ̀ kò lè gun igi tí kò sì lè fò
(xiii)     Ìjàpá ní kí ìyàwó òun di òun sí inú agbádá ẹtù bàbá òun; kí ó sì gbé e fún Àdán gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn tí òun fẹ́ fún un; kí ó sọ fún Àdán pé òun fi góòlù olówó iyebíye kan sínú ẹ̀wù náà fún ìyàwó rẹ̀; kí ó sì sọ fún Àdán pé òun kò sí nílé ni o
(xiv)     Ó ní kí ó kìlọ̀ fún Àdán pé kò gbọdọ̀ tú ẹ̀bùn náà wò lójú ọ̀nà o, àfi tí ó bá délé kí ó sì má jẹ́ kí ó jábọ́ o
(xv)      Yánníbo jẹ́ iṣẹ́ náà fún Àdán gẹ́gẹ́ bí ọkọ rẹ̀ ti rán an
(xvi)     Inú Àdán dùn púpọ̀; ó sì rò nínú rẹ̀ pé Ìjàpá fẹ́ràn òun gan-an ni tí ó fi lè fi ẹ̀wù ẹtù tọrẹ fún òun àti góòlù fún ìyàwó òun
(xvii)    Ìgbà tí Àdán délé pé kí òun ó tú ẹ̀wù ẹtù , kí òun wọ̀ ọ́ wò; kí ó sì fi góòlù jíṣẹ́ fún ìyàwó òun ni Ìjàpá rá pálá jáde láti inú aṣọ!
(xviii)  Báyìí ni Ìjàpá ṣe dọ́gbọ́n dé orí igi ní ilé Àdán

Candidates missed out marks in this question because they failed to give account of the folktale.