Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2021

Question 9


Rọ́ ìtàn bí wọ́n ṣe rí òkú Olúrón̄bí ní oko ẹgàn

Observation

Candidates were required to narrate how the corpse of Olúrón̄bí, one of the characters in the novel was discovered in the farm.

Bí wọ́n ṣe rí òkú Olúrónbí ní oko ẹgàn:

  1. Alàgbà Elújọba tọ Olúrónbí lọ láti ra ewé gbòdògì tí yóò fi bo ilé rẹ̀
  2. Olúrónbí kò ní ewé nílẹ̀ mọ́
  3. Ó ṣèlérí pé òun yóò lọ já ewé náà ní oko kí alàgbà Elújọba padà wá ní ọjọ́ kejì
  4. Ní ọjọ́ kejì alàgbà Elújọba retí Olúrónbí títí kò rí i
  5. Alàgbà Elújọba gba ilé Fogído tíí ṣe bàbá ọkọ Olúrónbí lọ
  6. Bí Fogído àti Diwúrà tí ó jẹ́ ìyàwó rẹ̀ ṣe jáde nílé wọn láti wá Olúrónbí lọ ni wọ́n pàdé alàgbà Elújọba
  7. Ó fi ẹjọ́ Olúrónbí sùn tọkọtaya pé Olúrónbí mọ̀-ọ́n-mọ̀ dá iṣẹ́ òun dúró ni
  8. Wọ́n sọ fún alàgbà Elújọba pé àwọn náà kò rí Olúrónbí àti ọmọ rẹ̀ láti òwúrọ̀ tí wọ́ṅ ti lọ sóko àti pé àwọn méjèèjì ni àwọn ń wá lọ nítorí pé kì í ṣe bẹ́ẹ̀
  9. Alàgbà Elújọba náà tẹ̀lé wọn lọ sí oko
  10. Wọ́n dé oko ẹgàn, wọn kò rí Olúrónbí
  11. Elújọba ṣà dédé gbọ́ ohùn aròbó/ọmọ kékeré kan tí ó ń ké lọ́nà jínjìn sí wọn
  12. Nígbà tí wọ́n dé ibi tí ọmọ náà ti ń ké, òkú Olúrónbí ni wọ́n bá nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ tí ọmọ rẹ̀ sì ń mu ọyàn àyà rẹ̀.
Most candidates captured the narrative very well and scored good marks