Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2021

Question 5

 

(a)   Dárúkọ márùn-ún nínú oríṣiríṣi ẹ̀yán tí ó wà nínú àpólà orúkọ
(b)     Fi àpẹẹrẹ kọ̀ọ̀kan kin ìdáhùn rẹ̀ ní 5(a) lẹ́yìn              
(d)     Lo àpẹẹrẹ kọ̀ọ̀kan ni 5(b) nínú gbólóhùn


 

Observation

Candidates are required to mention five types of qualifiers in a noun phrase in (a), give one example of each type of qualifier in (b) and use each example in an illustrative sentence in (c).

(a)      Àwọn ẹ̀yán tí ó wà nínú àpólà orúkọ
i.        Ẹ̀yán ajórúkọ: oníbàátan, alálàjẹ́
ii.       Ẹ̀yán aṣàpèjúwe
iii.      Ẹ̀yán aṣòǹkà
iv.      Ẹ̀yán aṣàfihàn
v.       Ẹ̀yán atọ́ka aṣàfihàn
vi.      Ẹ̀yán awẹ́-gbólóhùn

          (b)     Àpẹẹrẹ:
i.        bàbá, tíṣà, nọ́ọ̀sì, káfíńtà
ii.       rere, ńlá, dúdú
iii.      mẹ́ta, méjì
iv.      yìí, yẹn, wọ̀nyí, wọ̀nyẹn
v.       náà, gan-an, pàápàá
vi.      ti Òjó rà; tí à ń wá; tí bàbá kọ́

 

 

(d)   

Apẹẹrẹ

 Gbólóhùn àfiṣàpẹẹrẹ

bàbá (Ajórúkọ oníbàátan)

Ilé bàbá jóná/Wọ́n wó ilé bàbá

tíṣà (Ajórúkọ alálàjẹ́)

Kọ́lá tíṣà ti dé/Wọ́n pe Kọ́lá tíṣà.

rere

Ọmọ rere ni mí/ mo jẹ́ ọmọ rere.

    mẹ́ta, méjì

Àga mẹ́ta wà nínú yàrá/Mojoyin ra àga méjì

yìí

A ti ra ọkọ̀ yìí/Ọkọ̀ yìí wù mí

náà, gan-an, pàápàá

A rí Bọ́lá náà/gan-an/pàápàá

ti Òjó rà

Ilé tí Òjó rà tóbi./A fẹ́ lọ wo ilé tí Òjó rà.

 

Most candidates ignored this question. Those who attempted it failed to marry their answers in (a) with those in the (b) part of the question.
This led to poor performance.