Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2021

Question 10

 

Sọ àwọn ìpalára tí akéwì sọ pé màgòmágó ìdánwò ń fà gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ yọ nínú ewì “Màgòmágó Ìdánwò”

Observation

Candidates were tasked to explain the consequences of examination malpractices as evident in the poem.

Ìpalára tí akéwì sọ pé màgòmágó ìdánwò ń fà:

  1. Màgòmágó ìdánwò ń pa iná ètò-ẹ̀kọ́
  2. Ó máa ń sọ ni di ẹni yẹpẹrẹ nígbẹ̀yìn
  3. Ó máa ń ba aṣọ àlà ètò ẹ̀kọ́ orílẹ̀-èdè jẹ́
  4. Ó máa ń fa ikú àìtọ́jọ́
  5. Ó máa ń sọni di olóríburúkú
  6. Kì í jẹ́ kí á lè dáàbò bo ìwé-ẹ̀rí tí a gbà
  7. Ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó jáde ìwé mẹ́wàá kì í lè sọ èdè Òyìnbò tí ó já gaara
  8. Ó má  ń kọ́ àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́ tí wọn yóò fi di jàgùdà páálí
  9. Ó máa ń jẹ́ kí wọ́n lé ọmọ tí ọwọ́ bá tẹ̀ kúrò ní ilé-ẹ̀kọ́
  10. Ó máa ń sọni di àkọ̀tì láàrin ẹgbẹ́/ọ̀gbà
  11. Ó máa ń sọni di aláàbọ̀ ẹ̀kọ́
  12. Ó máa ń bani lórúkọ jẹ́
  13. O máa ń dójú ti ni
  14. Àtunbọ̀tan àwọn tíṣà tó kópa nínú màgòmágó ìdánwò kì í dára

This question was poorly answered by most candidates who, obviously, did not study the prescribed text. General guesses based on societal knowledge were made.