Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2021

Question 13

 

Ṣàlàyé lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ lórí bí a ṣe ń sìnkú ẹni tí àrá sán pa.

Observation

 

Candidates were required to describe the steps involved in the burial of the victim of thunder strike in the Yoruba traditional belief.

Bí a ṣe ń sìnkú ẹni tí àrá sán pa:

  1. Àwọn Yorùbá gbàgbọ́ pé Ṣàngó ni ó jà ní ibi tí àrá ti sán pa ènìyan
  2. Mọgbà àti àwọn ẹlégbẹ́ rẹ̀ ni ẹbí ẹni tí àrá sán pa yóò ránṣẹ́ sí
  3. Àwọn ẹbí ẹni tí àrá sán pa yìí kò gbọdọ̀ fọwọ́ kàn án
  4. Mọgbà yóò kọ́kọ́ wá ẹdùn àrá/òkò òòṣà náà síta
  5. Wọn yóò gba nǹkan ètùtù wọ̀nyí (àgbò méjì,ahun/Ìjàpá, ìgbín, igbá, orógbó, ẹmu, ọkọ́ àti epo) lọ́wọ́ mọ̀lẹ́bí ẹni tí àrá sán pa
  6. Ọjọ́ méje ni Mọgbà àti àwọn adóṣù Ṣàngó ẹgbẹ́ rẹ̀ yóò fi ṣe orò ìsìnkú ẹni tí àrá sán pa náà
  7. Àwọn ẹbí olóògbé ni yóò máa bọ́ àwọn adóṣù Ṣàngó fún ọjọ́ méjèèje yìí
  8. Ọkà/àmàlà, ọbẹ̀ gbẹ̀gìrì pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran ní wọn yóọ̀ máa fún àwọn adóṣù jẹ́
  9. Ìrọ̀lẹ́ ni àwọn mọ̀lẹ́bí olóògbé yóò máa jó kiri fún gbogbo ọjọ́ méjèèje yìí
  10. Àwọn alágbẹ̀dẹ ni yóò máa lu ọmọ owú tẹ̀lé wọn lẹ́yìn
  11. Odò tí ó bá súnmọ tòsí ni àwọn mọ̀lẹ́bí olóògbé yóò parí ijó wọn sí láti tọrọ àforíjì lọ́wọ́ Ṣàngó
  12. Lóru ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí gán-an ni àwọn adoṣù yóò ṣe aáyan òkú
  13. Gbogbo nǹkan ìní ẹni tí àrá sán pa ni wọn yóò gbà lọ́wọ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀.
  14. Wọ́n yóò gbẹ́ ilẹ̀ bíi sààréè lọ́gangan ibi tí àrá ti sán pa olóògbé
  15. Wọ́n yóò mú orí àgbò, ahun/ìjàpá, ìgbín pẹ̀lú ẹdùn àrá sínú kòtò náà
  16. Wọ́n yóò yí odó bo orí sààréè náà
  17. Ní ọjọ́ keje ni wọn yóò bọ òrìṣà láti mọ ìdí tí Ṣàngó fi bá ẹni tí àrá sán pa jà

Many candidates ignored this question while the few who attempted it performed poorly.