Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2021

Question 11

 

Ròyìn bí ayẹyẹ ìsìnkú bàbá àgbà ṣe lọ lóko.

 

Observation

 

Candidates were required to narrate the burial ceremony of baba in the village.

Bí ayẹyẹ ìsìnkú bàbá àgbà ṣe lọ lóko:

  1. Bàbá Àdìó wá sọ fún Àdìó pé bàbá àgbà ti kú
  2. Àdìó sọ fún bàbá pé owó pọ̀ ní ọwọ́ òun nítorí pé wọ́n ti dá òun dúró lẹ́nu iṣẹ́ ṣùgbọ́n ó ṣèlérí láti gbé bùkátà pósí rírà
  3. Àdìó àti Àbẹ̀ní pinnu láti gba àgbàálẹ̀ owó-oṣù mẹ́ta ní ibi tí Oyèládùn,ọmọ wọn, ti ń ṣe iṣẹ́ ọmọ-ọ̀dọ̀
  4. Ọládẹ̀jọ yá Àbẹ̀ní ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún náírà dípò àgbàálẹ̀ owó-oṣù láti fi ṣe òkú bàbá àgbà
  5. Nígbà tí wọ́n gbé pósí dé oko, òkìkí kàn torí pé wọn kò tíì gbé irú pósí bẹ́ẹ̀ wọ oko yìí rí
  6. Ní ibi tí wọ́n tẹ́ bàbá àgbà sí, ṣe ni àwọn ènìyàn ń garùn, tí wọ́n sì ń ṣàdúrà lóríṣiríṣi fún àwọn ọmọ òkú
  7. Gbogbo arúgbó ni wọ́n ń ṣàdúrà pé kí ẹ̀yìn ti àwọn náà dára bíi ti bàbá àgbà àti pé kí àwọn náà rí ọmọ tí yóò fi irú pósí bẹ́è sin àwọn
  8. Inú bàbá Àdìó gan-an dùn fún bí ìnáwó òkú bàbá òun ṣe rí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó pe Àdìó sí kọ̀rọ̀, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé báwo ló ṣe ṣe é; Àdìó dáhùn pé Ọlọ́run ló bo àṣírí.
  9. Àyànlékè fi ìlù dá bírà ní ọjọ́ náà
  10. Gbogbo ènìyàn ni wọ́n fi ẹsẹ̀ rajó tí wọ́n sì ń ṣàdúrà fún àwọn ọmọlóòkú
  11. Bí ayẹyẹ òkú bàbá àgbà ṣe lọ lóko nìyí


.