Yoruba Paper 2 WASSCE (PC 1ST), 2021

Question 8

    Kí ni ó fàá tí Orò fi máa ń jáde ní òru nìkan?
    Candidates were required to explain the reason why Oró goes out only at night.


Observation

Ìdí tí Orò fi máa ń jáde ní òru nìkan:
(i)      Òrìṣà ni Egúngún àti Orò jẹ́ nígbà ìwáṣẹ̀
(ii)      Ìbejì ni Egúngún àti Orò
(iii)     Ọkùnrin ni àwọn méjèèjì
(iv)     Orò lẹ̀gbọ́n, Egúngún làbúrò
(v)      Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni àwọn méjèèjì ń ṣe
(vi)     Ìyàwó wọn ni ó sì ń ta irè oko wọn lọ́dọọdún
(vii)    Ìyàwó Egúngún ń fi owó díẹ̀díẹ̀ pamọ́, ó sì ń raṣọfún ọkọ rẹ̀
(viii)   Onínà-án-kúnà-án obìnrin ni ìyàwó Orò, tìfun-lọ̀ràn ni, kì í rí owó fi pamọ́
(ix)     Ìyàwó Orò kì í raṣọ fún ọkọ rẹ̀
(x)      Ní ọjọ́ kan, Egúngún àti Orò fẹ́ẹ́ lọ sí òde
(xi)     Egúngún kó sínú aṣọ tí ó jíire ṣùgbọ́n Orò kò rí aṣọ gidi kan wọ̀
(xii)    Èyí mú kí Orò rí àṣìṣe aya rẹ̀
(xiii)   Orò mú àtòrì rọ̀jọ̀rọ̀jọ̀, ó kó o bo ìyàwó rẹ̀
(xiv)   Ìyàwó Orò sá, ó korí bọ igbó
(xv)    Orò lé e kò bá a nítorí pé ìhòhò ni Orò wà
(xvi)   Láti ìgbà náà ni Orò ti ń pe Ìyàwó yìí kágbó tí ó sì máa ń sọ pé ‘Bun-un-bun-un-bun-un’
(xvii)   Egúngún a máa jáde láàárọ̀, lọ́sàn-án tàbí lálẹ́ nítorí pé aṣọ tí ó jíire ni ó máa ń wọ̀ sọ́rùn.
(xviii)  Òru nìkan ni Orò fi ń rìn jáde nítorí ipò oníhòòhò tí ó máa ń wà
(xix)   Ìdí nìyí tí Orò fi máa ń jáde ní òru nìkan.

Only a few candidates attempted this question.  Their responses to this question portrayed failure to study the text.