Yoruba Paper 2 WASSCE (PC 1ST), 2021

Question 12

    Ṣàlàyé ìwúlò èsúsú gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìranra-ẹni-lọ́wọ́ nínú àṣà ìbílẹ̀ Yorùbá


Observation

Candidates were required to explain the importance of contributory scheme in the Yoruba traditional custom.

 

                    Ìwúlò Èsúsú gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà Ìranraẹni-lọ́wọ́:

  1. Èsúsú jẹ́ ọ̀nà kan tí à ń gbà fi owó pamọ́ fún níná lọ́jọ́ iwájú/ọ̀nà kan láti pọn omi sílẹ̀ de òǹgbẹ
  2.      Ìbẹ̀rẹ̀ èésú dídá ni wọn yóò ti ṣe ìpinnu lórí iye ti ẹni kọ̀ọ̀kan yóò máa dá àti ọjọ́ tí wọn yóò máa kó èésú.
  3.      Iye tí gbogbo ìjókòó bá fẹnu kò sí ni ẹnikọ̀ọ̀kan yóò máa kó
  4.      Kò sí ẹni tí í kó èésú tán kí ó má dá èésú mọ́
  5.      Olórí èésú ni alága èésú
  6.      Ó máa ń fa ìrẹ́pọ̀ láàrin àwọn ènìyàn tó ń kópa nínú rẹ̀
  7. Ó máa ń jẹ́ kí ènìyàn múra sí iṣẹ́
  8. Ó máa ń jẹ́ kí akópa ṣeé fi ọkàn tán
  9.      Ó máa ń bo àṣírí/ran àwọn akópa lọ́wọ́
  10.      Ó máa ń jẹ́ kí ènìyàn kó ara rẹ̀ ní ìjánu/ ṣọ́ owó ná
  11.      Ó máa ń tú àṣírí ẹni tí kò ṣeé bá dòwò pọ̀
  12. Ó fi ìran Yorùbá hàn gẹ́gẹ́ bí àwùjọ ẹ̀dá tí ó ní àròjinlẹ̀/tí ó mọ̀ nípa pàtàkì ìfọwọ́wẹwọ́
  13. Ó máa ń ran akópa lọ́wọ́ láti gbé nǹkan rere ṣe lásìkò
  14. Kì í jẹ́ kí ìnáwó kankan bá wọn ní òjijì/ẹ̀jafùú
  15. Ó máa ń jẹ́ kí ọkàn àwọn akópa balẹ̀

Candidates who attempted this question performed fairly well.