Yoruba Paper 2 WASSCE (PC 1ST), 2021

Question 11

    Ìhà wo ni Àbẹ̀ní kọ sí àìníṣẹ́-lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀


Observation

Candidates were required todescribe Abeni’s attitude towards her husband’sloss of his paid employment.

Ìhà tí Àbẹ̀ní kọ sí àìníṣẹ́lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀:

  1. Àdìó ni ọkọ Àbẹ̀ní
  2. Wọ́n bí ọmọbìnrin kan tí wọn sọ ní Oyèládùn
  3. Iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ Àdìó
  4. Kò rí owó oúnjẹ fún ìyàwó rẹ̀ mọ́
  5. Kò rí owó rán ọmọ rẹ̀ lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ mọ́
  6. Àbẹ̀ní kì í tètè gbé oúnjẹ fún ọkọ rẹ̀ mọ́
  7. Àbẹ̀ní kò ka ọkọ rẹ̀ sí mọ́/àṣẹ tí Àdìó bá pa, Àbẹ̀ní kì í tẹ̀lé e
  8. Àbẹ̀ní máa ń gbé ọjà lé ọmọ rẹ̀ lórí láti kiri kí wọ́n lè rí owó fi jẹun
  9. Àbẹ̀ní pinnu láti mú ọmọ rẹ̀ lọ ṣe iṣẹ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ lọ́dọ̀ Àdíjá láìfi tó ọkọ rẹ̀ létí
  10. Àbẹ̀ní kì í dágbére fún ọkọ rẹ̀ kí ó tóó jáde nílé
  11. Àbẹ̀ní fi owó tí Ọládẹ̀jọ fún un ra oúnjẹ wálé, kò sì fún ọkọ rẹ̀ jẹ nínú rẹ̀
  12. Àbẹ̀ní máa ń sọ ọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí ọkọ rẹ̀
  13. Nígbà tí bàbá ọkọ rẹ̀ kú, Àbẹ̀ní gba ọkọ rẹ̀ nímọ̀ràn kí wọ́n lọ gba àsansílẹ̀ owó-oṣù mẹ́ta ọmọ wọn kí wọ́n lè rí owó ṣe òkú
  14. Àbẹ̀ní kò lè kó ara rẹ̀ ní ìjánu láti má ṣe àgbèrè

Candidates who attempted the question performed poorly.