Yoruba Paper 2 WASSCE (PC), 2023

Question 7

Ṣàlàyé mẹ́wàá nínú kókó ọ̀rọ̀ tó jẹ yọ nínú “Oríkì Ìran Ìlọ̀kọ́”

Candidates were required to explain ten important facts highlighted in the poetry of the Ìlọ́kọ́ lineage.

  1. Ìṣẹ́ fífi idà bẹ́ ọ̀daràn lórí fún ọba ni ìran yìí ń ṣe
  2. Èyí ni wọ́n ṣe ń kì wọ́n báyìí pé “Oníṣẹ́-ikú, ọmọ Atẹkojọ́balólele”
  3. Ìran oníṣọ̀nà-aláwọ tí ó gbé Ọya lórí ni tiwọn
  4. Wọ́n máa ń gbé orí ẹni tí òrìṣà bá pa dání tí wọ́n bá ń yọ ayọ̀ òrìṣà tó pa ènìyàn burúkú
  5. Ọya ni ìran yìí máa ń bọ
  6. Wọ́n tún máa ń bọ Ifá pẹ̀lú
  7. Olówó ni wọ́n ní ìran yìí
  8. Ọ̀pọ̀ ọmọ ìran yìí ló máa ń di akọni
  9. Ìran yìí fẹ́ràn ọtíkà
  10. Obì ni wọ́n fi ń bọ idà tí wọ́n fi ń bẹ́ orí ọ̀daràn
  11. Èèwọ̀ ìran yìí ni pé wọn kò gbọdọ̀ ṣẹ́ aṣọ lórí lọ sí igbó Ọya

 

The candidates who attempted this question failed to give the highlighted important facts about the Ìlọ̀kọ́ lineage