Yoruba Paper 2 WASSCE (PC), 2023

Question 13

Àwọn ẹ̀kọ́ two ni àwọn ọmọ-ọdẹ máa ń kọ́ níbi ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọdẹ?

Candidates were required to state all the lessons that hunters usually acquire while on training.

  1. Yóò kọ́ nípa lílo onírúurú irinṣẹ́ ọdẹ
  2. Yóò kọ́ bí a ti ń fi ojú sun ẹran tí ìbọn, ọfà tàbí àkàtàǹpó kò fi níí tàsée rẹ̀
  3. Yóò kọ́ bí a ṣe ń gẹ̀gùn àti bí a ṣe ń lúgọ de ẹranko tí a fẹ́ẹ́ pa
  4. Yóò kọ́ bí a ṣe ń mọ̀ pé ẹranko ń bọ̀ láti apá ibì kan
  5. Yóò kọ́ bí a ṣe ń rìn nínú igbó tí a kò fi níí lé ẹran lọ
  6. Yóò kọ́ bí a ṣe ń yin ìbọn tí kò níí ba ọdẹ mìíràn tí wọn jọ lọ sí ìgbẹ́
  7. Yóò kọ́ nípa ọ̀gangan ibi tí a máa ń yin ìbọn sí ní ara ẹran tí yóò fi lè pa á ní àpafọ̀n tí ẹran náà kò fi níí gbé ọgbẹ́ ìbọn sá lọ/fi ẹ̀tù ṣòfò
  8. Yóò kọ́ bí ọdẹ ṣe ní láti máa sọ̀rọ̀ nínú igbó; kí ẹranko má bàá gbọ́ ohùn ọdẹ kí ó sì sá lọ
  9. Ó ní láti kọ́ nípa ètùtù ṣíṣe fún ẹranko abàmì tí ó bá pa
  10. Yóò kọ́ nípa àwọn èèwọ̀ ọdẹ
  11. Ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọdẹ gbọ́dọ̀ kọ́ ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni, ìgboyà, ìlawọ́, ìforítì, sùúrù àti ìjáfáfá
  12. Yóò kọ́ nípa oríṣiríṣi oògùn tí ọdẹ fi ń ṣe agbára
  13. Yóò kọ́ nípa àwọn igbó àìwọ̀ tí ó wà ní àrọ́wọ́tó
  14. Yóò kọ́ bí a ṣe ń bọ̀wọ̀ fún àwọn àgbà ọdẹ
  15. Yóò kọ́ bí a ṣe ń bọ Ògún
  16. Yóò kọ́ bí a ṣe ń ní ìfura
  17. Yóò kọ́ bí a ṣe ń lo ajá láti dẹ ìgbẹ́
  18. Yóò kọ́ bí a ṣe ń dẹ pàkúté/pańpẹ́/gbóró, ìrín, ọṣọ́, ìgèrè, abbl
  19. Yóò kọ́ bí a ṣe ń kun ẹran tí a bá pa
  20. Yóò kọ́ bí a ṣe ń yan ẹran tí a pa

 

Some of the candidates who attempted this question did justice to it.