Yoruba Paper 2 WASSCE (PC 2ND), 2022

Question 6

    Nínú ìtàn “Ìjàpá, Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ àti Àdìẹ”, rọ́ ìtàn bí Adìẹ ṣe di èrò ilé.


Observation

 

Candidates were required to narrate how Adìẹ, one of the characters in the folktale became a domestic character.

Adìẹ ṣe di èrò ilé nínú ìtàn “Ìjàpá, Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ àti Adìẹ”:
(i)         Ní ìgbà kan, ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ àti Ìjàpá í ṣe
(ii)        Àwọn ẹranko kéékèèké ni Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ máa ń fi ṣe oúnjẹ jẹ
(iii)       Ìjàpá máa ń bá àwọn ẹranko kéékèèké wọ̀nyí ṣeré, yóò sì fi ọgbọ́n tàn wọ́n lọ sọ́dọ̀ Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ láti pa jẹ
(iv)       Nítorí èyí, Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ fẹ́ràn Ìjàpá gan-an, a sì máa dáàbò bò ó lọ́wọ́ àwọn ẹranko tí ó bá fẹ́ fìyà jẹ ẹ́
(v)        Nígbà tí ó yá, Ìjàpá ṣàkíyèsí pé nígbàkúùgbà tí òun bá tan Àkùkọ dé ọ̀dọ̀ Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, sísá ni Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ máa ń sá dípò kí ó pa á jẹ
(vi)     Ìjàpá wádìí ohun tí ó fà á tí Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ fi ń yẹra fún Àkùkọ dípò kí ó pa á jẹ
(vii)      Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ dáhùn pé nítorí iná tí Àkùkọ gbé lórí kí ó má bàá jóun lọ́wọ́ ni òun ṣe ń yẹra fún un
(viii)     Ìjàpá jẹ́ kí Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ mọ̀ pé ogbe tí ó jẹ́ ẹran jọ̀bọ̀jọ̀bọ̀ ni ó wà lórí Àkùkọ
(ix)       Ìjàpá ki Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ láyà pé kí àwọn jọ lọ fọwọ́ kan orí Àkùkọ lálẹ́ nígbà tí ó bá ti sùn lọ fọnfọn
(x)        Ìjàpá sọ fún Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ pé òun ni òun yóò kọ́kọ́ sún mọ́ Adìẹ tí òun yóò fọwọ́ kan ogbe orí rẹ̀ bóyá yóò jó òun tàbí kò níí jó òun
(xi)       Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ gbà bẹ́ẹ̀, ó sì tẹ̀lé Ìjàpá ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀; ó rò pé Ìjàpá fẹ́ tan òun pa ni
(xii)      Nígbà tí wọ́n dé ọ̀hún, Àkùkọ ti sùn fọnfọn bí igi àjà
(xiii)     Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ tàdí mẹ́yìn ó ń wo Ìjàpá, kò jẹ́ sún mọ́ Àkùkọ
(xiv)     Bí Ìjàpá ti dé ọ̀dọ̀ Àkùkọ ni ó rọra di ogbe orí rẹ̀ mú kí Àkùkọ má baá jí, kí ó sì sá lọ
(xv)      Ìjàpá fi ọwọ́ pe Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kó máa bọ̀ wáá di ogbe orí Àkùkọ mú
(xvi)     Àyà Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ń lù kìkì; bó ti ń sún síwájú ló tún ń sá padà sẹ́yìn
(xvii)    Nígbà tí ó ṣe, Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ sún mọ́ Àkùkọ, ó rí i pé Ìjàpá ko mú ọwọ́ kúrò lára ogbe orí Àkùkọ èyí tí Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ń pè ní iná
(xviii)   Nítorí náà, àyà kò ó díẹ̀ láti di ogbe orí Àkùkọ mú
(xix)     Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù ṣì ń ba Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, Ìjàpá sọ oríṣiríṣi fún un láti kì í láyà
(xx)      Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà ṣe bí akin, ó pa kuuru sí Adìẹ, Ó fọwọ́ kan ogbe orí rẹ̀, ó sì rí i pé ó tutù àti pé ẹran ni ó wà níbẹ̀
(xxi)     Pàtì ló fà á já, ó sọ ọ́ sẹ́nu, ó jẹ ẹ́, ó dùn mọ lẹ́nu
(xxii)    Adìẹ tají lójijì, orí ta á, ẹ̀jẹ̀ ń kán pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ látorí rẹ̀, ó fọwọ́ pa á, ogbe orí rẹ̀ ti lọ
(xxiii)   Bí ó ti wo iwájú ni ó rí Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ tí ó tún ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀
(xxiv)   Kíá, Àkùkọ bu eré dà sí i; Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ gbá, ó fi yá a
(xxv)    Báyìí ni Àkùkọ sá títí tí ó fi dé ahéré àgbẹ̀ kan; àgbẹ̀ yìí ni ó gba Adìẹ sílẹ̀ lọ́wọ́ Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀
(xxvi)   Láti ọjọ́ náà ni Àgbẹ̀ tí ń sin Adiẹ ti Adìẹ sì di èrò ilé 

Many of the Candidates who attempted this question could not narrate the story of how the chicken became a domestic animal as evident in the text because of lack of exposure to the text.