Yoruba Paper 2 WASSCE (PC 2ND), 2022

Question 11

    Rọ́ ìtàn bí àṣírí Àbẹ̀ní ṣe tú


Observation

Candidates were required to narrate how Àbẹ̀ní, a character, in the play was caught in the act of adultery.

Bí àṣírí Àbẹ̀ní ṣe tú:

  1. Ọ̀dọ̀ Ọládẹ̀jọ, ọkọ Àlàájà, ni Àdìó, ọkọ Àbẹ̀ní, ti wá ń ṣiṣẹ́
  2. Àdìó á máa lọ sí ìrìn-àjò láti ibi iṣẹ́ rẹ̀ tuntun náà
  3. Lọ́jọ́ kan tí Àdìó lọ sí Ìdí-Ìrókò ni Ọládẹ̀jọ wá Àbẹ̀ní wálé
  4. Àbẹ̀ní fi hàn pé inú òun kò dùn sí wíwá tí Ọládẹ̀jọ wá òun wá sí ilé
  5. Ọládẹ̀jọ wọlé tọ Àbẹ̀ní nígbà tí ìyẹn lọ bu omi wá fún un
  6. Bàbá-ọkọ Àbẹ̀ní wá bẹ ọmọ rẹ̀ wò
  7. Bàbá wọlé, ó bá báàgì kan tí wọ́n gbé kalẹ̀ ní pálọ̀
  8. Ó yẹ̀ ẹ́ wò; ó rò pé ti ọmọ òun ni
  9. Ó pè pè pè, kò rí ẹni dá a lóhùn
  10. Ó pinnu láti gbé báàgì náà lọ láti fi kọ́ ọmọ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ pé kò yẹ kí ó máa ṣe bẹ́ẹ̀ gbé ohun pàtàkì sílẹ̀
  11. Bí Ọládẹ̀jọ ṣe gbọ́ pé bàbá fẹ́ẹ́ gbé báàgì lọ ló sáré jáde láti inú yàrá
  12. Ó ya bàbá lẹ́nu láti rí ọkùnrin àjèjì nínú ilé Àdìó, ọmọ rẹ̀
  13. Bàbá fi igbe ta;ó ń kígbe olè lé Ọládẹ̀jọ lórí
  14. Ọládẹ̀jọ pe Àbẹ̀ní jáde láti inú yàrá
  15. Báyìí ni àṣírí Àbẹ̀ní ṣe tú

 

Candidates who attempted the question performed fairly well.