Yoruba Paper 2 WASSCE (PC 1ST), 2020

Question 9

    Ṣe àlàyé bí ọ̀rọ̀ Òbí ṣe já sí ayọ̀ nígbẹ̀yìn.


Observation

Candidates were expected to explain how Òbí, the lead character, in the novel became successful

Àlàyé bí ọ̀rọ̀ Òbí ṣe já sí ayọ̀ nígbẹ̀yìń:

  1. Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ onípò kejì ní ìlú Ilé-Ifẹ̀.
  2. Ó ń ṣiṣẹ́; owó sì ń dúró lọ́wọ́ rẹ̀.
  3. Ó ń tọ́jú ìyàwó rẹ̀; ó si ń gbọ́ bùkátà lórí àwọn àbúrò rẹ̀.
  4. Aya rẹ̀ fi ọmọbìnrin ṣe àkọ́bí (ọwọ́-ẹ̀rọ̀ ni èyí já sí).
  5. Ó wọ ilé-ẹ̀kọ́ gíga; ó gboyè àkọ́kọ́ nínú ìmọ̀ agbẹ́gilére.
  6. Lẹ́yìn èyí ó ń rí iṣẹ́ agbẹ́gilére gbà èyí tí ó jẹ́ kí owó máa pọ̀ sí i ní ọwọ́ rẹ̀.
  7. Ó ra mọ́tò.
  8. Ó ra ilẹ̀; ó bẹ̀rẹ̀ ilé kíkọ́; ó sì parí rẹ̀.
  9. Ìyàwó rẹ̀ tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀.
  10. Ó di olówó, ó sì rántí mẹ̀kúnnù.
  11. Ọba ìlú wọn ránṣẹ́ pè é; wọ́n sì fi oyè dá a lọ́lá.
  12. Báyìí ni ọ̀rọ̀ òbi ṣe di ayọ̀ nígbẹ̀yìn.

 

Candidates’ performance in this question was commended by the chief examiner.