Yoruba Paper 2 WASSCE (PC 1ST), 2020

Question 7

    Nínú oríkì “Ìran Arẹ̀sà”, Báwo ni Ìran Arẹ̀sà ṣe dá ẹ̀kù tí wọ́n ti ń ṣe epo sílẹ̀?


Observation

Candidates were required to narrate how the lineage, Arẹ̀sà created the palm oil manufacturing house as it is described in the poem of this lineage.

Bí ìran Arẹ̀sà ṣe dá ẹkù tí wọ́n ti ń ṣepo sílẹ̀:

 

  1. Ọ̀pẹ kan wà ní ìdí odò ní Ajeté Ilé
  2. Ọ̀pẹ yìí pọ́n odi ẹyìn mẹ́fà.
  3. Wọ́n kọ odi ẹyìn yìí sílẹ̀..
  4. Wọ́n ń ronú ibi tí wọn yóò gbé e lọ láti fi ṣepo.
  5. Àgbẹ̀ kan tí ó ń ti oko ẹgàn bọ̀ là wọ́n lọ́yẹ̀.
  6. Ó ní kí wọ́ṅ gbẹ́ ilẹ̀ kan bìrìkòtò, bìrìkótó.
  7. Ó sọ fún wọn pé kí wọ́n máa pe ibẹ̀ ní ẹkù epo.
  8. Wọ́n  ṣe bí àgbẹ̀ yìí ti wí fún wọn.
  9. Wọ́n wá ń pe ibẹ̀ ní ẹkù epo.
  10. Báyìí ni ìran Arẹ̀sà ṣe dá ẹkù tí wọ́n ti ń ṣe epo sílẹ̀