Yoruba Paper 2 WASSCE (PC 1ST), 2020

Question 11

    Báwo ni ìpèdè “Àkẹ́jù níí ba ọmọ olówó jẹ́” ṣe bá Kúnbi mu?


Observation

Candidates were expected to explain the adage “Àkẹ́jù níí ba ọmọ olówó  jẹ́ and how it is related to Kúnbi, one of the lead characters in the play.


Bí ìpèdè “àkẹ́jù níí ba ọmọ olówó jẹ́” ṣe bá Kúnbi mu:

      1. Olówó paraku ni àwọn òbí Kúnbi.
      2. Àwọn òbí Kúnbi kò bìkítà nípa bí ó ṣe ń lo ìgbésí ayé rẹ̀.
      3. Orí ìrìn láti lọ ra ọjà ní ìyá Kúnbi máa ń wà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà.
      4. Wọ́n gba Kúnbi láyè láti yọ ayọ̀pọ̀rọ́ nítorí pé òun nìkan ni wọ́n bí.
      5. Kúnbi kò gbájú mọ́ ìwé rẹ̀ ṣùgbọ́n àwọn òbí rẹ̀ kò bá a wí bi ó ṣe ń jayé kiri.
      6. Àwọn òbí rẹ̀ fi owó bà á jẹ́.
      7. Ohunkóhun tí ó bá fẹ́ ni àwọn òbí rẹ̀ ń ṣe fún un.
      8. Wọ́n gbà fún un láti lọ ka ìwé awúrúju ní ìlú òyìnbó.
      9. Wọn kò kọ́ ọ ní ẹkọ́-ilé kankan, àwọn òṣìṣẹ́ ni wọ́n gbà fún un láti máa ṣe iṣẹ́ ilé fún un.

Candidates who attempted the question did justice to it.