Yoruba Paper 2 WASSCE (PC 1ST), 2020

Question 5

    Fi gbólóhùn kọ̀ọ̀kan ṣe àpẹẹrẹ oríṣìí ẹ̀yán wọ̀nyí:

    (a)aṣàpèjúwe;
    (b)ajórúkọ oníbàátan;
    (d) ajórúkọ alálàjẹ́;
    (e) aṣòǹkà òǹkaye;
    (ẹ) aṣòǹkà òǹkapò;
    (f) aṣòǹkà àgbájọ;
    (g) aṣòǹkà ìpín;
    (gb) aṣàfihàn;
    (h)atọ́ka aṣàfihàn; (i) awẹ́-gbólóhùn aṣàpèjúwe

Observation

Candidates were required to give example of one sentence each containing the different forms of modifiers.


S/N

Oríṣi Ẹ̀yán

Àpẹẹrẹ Gbólóhùn

a

aṣàpèjúwe

Bọ́lá ra ajá dúdú.

b

ajórúkọ oníbàátan

Owó Dúpẹ́ wà lọ́wọ́ mi.

d

ajórúkọ alálàjẹ́

Dókítà òyìnbó ń bọ̀.

e

aṣọ̀ǹkà òǹkaye

Kílààsì kejì ni mo wà.

aṣòǹkà òǹkapò

Kílààsì kejì ni mo wà.

f

aṣòǹkà àgbájọ

Má ṣe jẹ ẹja méjèèjì.
mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, márààrún, abbl.

g

aṣòǹkà ìpín

Ọmọ mẹ́ta mẹ́ta ni ewúrẹ́ ìyá àgbà máa ń bí.

gb

aṣàfihàn

Ajá yẹn wù mí.
yìí, wọ̀nyí, wọ̀nyẹn, wọ̀n-ọnnì, ọ̀hún, nì

h

atọ́ka aṣàfihàn

Olùbẹ̀wò náà kò tètè dé.
gan-an, pàápàá, nìkan, kẹ̀, kan náà

i

awẹ́-gbólóhùn aṣàpèjúwe

Wọ́n gba ilé tí bàbá Òjó kọ́.

 

 

                 Only a few of the candidates who tackled this question were able to give examples of sentences with the different forms of modifiers