Yoruba Paper 2 WASSCE (PC), 2022

Question 7

 

Kí ni ọ̀kọrin sọ nípa ìran Ọ̀bọ̀lọ́?

Observation

Candidates were required to explain how the poet described the Ọ̀bọ̀lọ́ lineage.

Ohun tí ọ̀kọrin sọ nípa Ìran Ọ̀bọ̀lọ́:

  1. Àjẹ́ pọ̀ nínú ìran yìí.
  2. Àjẹ́ kò gbọdọ̀ da ìran yìí láàmú.
  3. Wàhálà/ìdààmú ni fún ẹni tí ó bá ṣẹ ìran yìí.
  4. Ẹni tí kò bá fi tiwọn ṣe kò lè ṣe àṣeyọrí lórí ilẹ̀ wọn.
  5. Àwọn àjẹ́/òṣòròǹgà yìí a máa jẹ ẹran ènìyàn tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀/bọ̀lọ̀bọ̀lọ̀.
  6. Kò sí ibi tí wọn kò lè gbà wọlé tàbí gbà jáde láìgba àṣẹ.
  7. Òrìṣà ìran yìí ni Eji (Òjò).
  8. Tí wọ́n bá fún ènìyàn ní nǹkan kékeré, wọn yóò fi gba ńlá padà lọ́wọ́ onítọ̀hún.
  9. Wọ́n a máa rílé-ríta/mọ bí nǹkan ṣe ń lọ níbi gbogbo.
  10. Wọ́n mọ bí wọ́n ti ń tọ́jú ọmọ tiwọn ṣùgbọ́n wọ́n lè fi ojú ọmọ ẹlòmíì rí èèmọ̀/màbo.

 

The candidates who attempted this question failed to give detailed analysis of how the poet described the Ọ̀bọ̀lọ́lineage.