Yoruba Paper 2 WASSCE (PC), 2022

Question 11

 

Ìhà wo ni Àbẹ̀ní kọ sí owó tí Bọ̀sípò fún Oyèládùn?

Observation

 

Candidates were required to explain Àbẹ̀ní‘s disposition to the money Bosipo gave Oyeladun, her daughter.

Ìhà tí Àbẹ̀ní kọ sí owó tí Bọ̀sípò fún Oyèládùn:

  1. Àbẹ̀ní béèrè pé níbò ni Oyèládùn ti rí adúrú owó náà.
  2. Ó tún béèrè pé báwo ni Bọ̀sípò ti jẹ́ sí Oyèládùn.
  3. Ó tún  bi í pé níbo ló rò pé Bọ̀sípò ti rówó; ṣé Bọ̀sípò ń ṣiṣẹ́ lójú ẹ̀ ni?
  4. Ó ní òun ò fẹ́ pálapàla!
  5. Àbẹ̀ní sọ pé irú owó ńlá bẹ́ẹ̀ kò lè jẹ́ owó tí wọ́n gbàgbé sílẹ̀ nílé Bọ̀sípò.
  6. Àbẹ̀ní sọ pé ó ní láti jẹ́ pé olè ni Bọ̀sípò ń jà.
  7. Àbẹ̀ní gba Oyèládùn nímọ̀ràn pé kò yẹ kí ó gba irú owó bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ Bọ̀sípò nítorí pé òun kò rán an lọ jalè nílé onílé.
  8. Àbẹ̀ní sọ pé kí Oyèládùn lọ dá owó náà padà fún Bọ̀sípò.
  9. Àbẹ̀ní béèrè lọ́wọ́ Oyèládùn pé tí àwọn òbí Bọ̀sípò bá mú un, tí ó wá sọ pé ìwọ lòun ń kó owó fún ńkọ́?
  10. Àbẹ̀ní sọ pé òun ò lè ṣogun olè ṣùgbọ́n òun yóò bá Oyèládùn fi owó náà pamọ́ títí tí ọ̀rọ̀ yóò fi lójú.
  11. Àbẹ̀ní kìlọ̀ fún Oyèládùn pé kí ó ṣọ́ra fún Bọ̀sípò.
  12. Àbẹ̀ní sọ fùn Oyèládùn pé kí ó kọjú mọ́ owó ilé-ìwé tí ó wá lọ síbẹ̀ nítorí pé bàbá tí a  bá bá rogun làá kọjú mọ́.

Candidates who attempted the question performed fairly well.