Yoruba Paper 2 WASSCE (PC), 2022

Question 12

 

(a)      Ṣeàlàyé ní ṣókí ìhà tí àwọn Yorùbá kọ sí ọ̀ràn dídá láyé àtijọ́.

(b)     Ṣeàlàyé ìjìyà tàbí ìdájọ́ ìbílẹ̀ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀nyí:
(i)  Ìpànìyàn
(ii)Àgbèrè ṣíṣe

iii) Olè jíjà
(iv)  Èké Ṣíṣe
(v) Jìbìtì lílù

   (vi) Kí ọba tàpá sí òfín ìlú

Observation

Candidates were required to describe the view of the Yoruba traditional society to crime in the olden days in (a) and to state the punishment for each of the crimes listed in (b).

(a)      ÌhàtíàwọnYorùbákọsíọ̀ràndídáláyéàtijọ́

Yorùbá ní ìgbàgbọ́ nínú ìdájọ́ òdodo. Gbogbo ọ̀ràntíènìyànbádá ló ní ìdájọ́/ìjìyà lábẹ́ ètòìṣàkósoìlú. Wọn kì í fi ẹjọ́ ṣègbèrárá.

          (b)     Ìjìyà/ìdájọ́ ìbílẹ̀ fúnọ̀kọ̀ọ̀kanàwọnẹ̀ṣẹ̀ tíènìyànlèdá


S/N

       Ẹ̀ṣẹ̀

           Ìjìyà tàbí ìdájọ́ìbílẹ̀

i

Ìpànìyàn

Bíbẹ́ orí ọ̀daràn sí ìdí Ògún/síso ọ̀daràn rọ̀ sínú igbó
Orò títí tí yóò fi kú.

ii

Àgbèrè ṣíṣe

Tí ó bá jẹ́ onílélọ́kùnrin, wọn yóò ta á lójì.
Tí ó bá jẹ́ àlejòlọ́kùnrin, wọn yóò lé e kúrò ní ìlú.
Tí ó bá jẹ́ obìnrin, wọ́n lè nà án lẹ́gba ní ìta gban̄gba.

iii

Olè jíjà

Wọ́n lè fi olè sínú túúbú.
Wọ́n lè lé e kúrò ní ìlú.
Ẹni tó jà lólè lè fi ìyà ìdákọ́ńkọ́ jẹ ẹ́.

iv

Èké Ṣíṣe

Wọ́n lè ku eérú èké lé e lórí nígban̄gba.
Wọ́n lè yọ ọ́ kúrò nínú ẹgbẹ́.

v

Jìbìtì lílù

Sísan owó ìtanràn; dídá owó padà.
Wọ́n lè lé e kúrò ní ìlú.
Wọ́n lè yọ ọ́ kúrò nínú ẹgbẹ́.

vi

Kí ọba tàpá sí òfín ìlú

Wọ́n lè ní kí ọba ṣígbá-ìwàwò/ṣe bíọkùnrin.
Bíkòbáṣígbá-ìwàwò/ ṣe bíọkùnrin, wọ́n yóòníkí ó fi oríoyè/ìlúsílẹ̀.

Only a few of the candidates who attempted this question grasped the requirement of the question.